Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 23:26-41 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Bí wọ́n ti ń fa Jesu lọ, wọ́n bá fi ipá mú ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene tí ó ń ti ìgbèríko kan bọ̀. Wọ́n bá gbé agbelebu rù ú, wọ́n ní kí ó máa rù ú tẹ̀lé Jesu lẹ́yìn.

27. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé Jesu, pẹlu àwọn obinrin tí wọn ń dárò, tí wọn ń sunkún nítorí rẹ̀.

28. Nígbà tí Jesu yipada sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ẹ má sunkún nítorí tèmi mọ́; ẹkún ara yín ati ti àwọn ọmọ yín ni kí ẹ máa sun.

29. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ẹ óo sọ pé, ‘Àwọn àgàn tí kò bímọ rí, tí wọn kò sì fún ọmọ lọ́mú rí ṣe oríire.’

30. Nígbà náà ni wọn yóo bẹ̀rẹ̀ sí máa sọ fún àwọn òkè ńlá pé, ‘Ẹ wó lù wá,’ wọ́n óo sì máa sọ fún àwọn òkè kékeré pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀.’

31. Nítorí bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí fún igi tútù, báwo ni yóo ti rí fún igi gbígbẹ?”

32. Wọ́n tún ń fa àwọn arúfin meji kan pẹlu rẹ̀, láti lọ pa wọ́n.

33. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì.

34. Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.”Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.

35. Àwọn eniyan dúró, wọ́n ń wòran. Àwọn ìjòyè ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé, “O gba àwọn ẹlòmíràn là; gba ara rẹ là bí ìwọ bá ni Mesaya, àyànfẹ́ Ọlọrun.”

36. Àwọn ọmọ-ogun náà ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n fún un ní ọtí pé kí ó mu ún.

37. Wọ́n ní, “Bí ìwọ bá ni ọba àwọn Juu, gba ara rẹ là.”

38. Wọ́n kọ àkọlé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí òkè orí rẹ̀ pé, “Èyí ni ọba àwọn Juu.”

39. Ọ̀kan ninu àwọn arúfin tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ ń sọ ìsọkúsọ pé, “Ṣebí ìwọ ni Mesaya! Gba ara rẹ là kí o sì gba àwa náà là!”

40. Ṣugbọn ekeji bá a wí, ó ní, “Ìwọ yìí, o kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ìdájọ́ kan náà ni wọ́n dá fún un bíi tiwa.

41. Ní tiwa, ó tọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí èrè iṣẹ́ wa ni à ń jẹ. Ṣugbọn òun ní tirẹ̀ kò ṣẹ̀ rárá.”

Ka pipe ipin Luku 23