Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 23:10-24 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin dúró níbẹ̀, wọ́n ń tẹnu mọ́ ẹ̀sùn tí wọn fi kàn án.

11. Hẹrọdu ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ń kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n gbé ẹ̀wù dáradára kan wọ̀ ọ́; Hẹrọdu bá tún fi ranṣẹ pada sí Pilatu.

12. Ní ọjọ́ náà Hẹrọdu ati Pilatu di ọ̀rẹ́ ara wọn; nítorí tẹ́lẹ̀ rí ọ̀tá ni wọ́n ń bá ara wọn ṣe.

13. Pilatu bá pe àwọn olórí alufaa, ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan jọ,

14. ó sọ fún wọn pé, “Ẹ fa ọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ mi bí ẹni tí ó ń ba ìlú jẹ́. Lójú yín ni mo wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, tí n kò sì rí àìdára kan tí ó ṣe, ninu gbogbo ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án.

15. Hẹrọdu náà kò rí nǹkankan wí sí i, nítorí ńṣe ni ó tún dá a pada sí wa. Ó dájú pé ọkunrin yìí kò ṣe nǹkankan tí ó fi yẹ kí á dá a lẹ́bi ikú.

16. Nítorí náà nígbà tí a bá ti nà án tán, n óo dá a sílẹ̀.” [

17. Nítorí ó níláti dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún wọn ní àkókò àjọ̀dún.]

18. Ṣugbọn gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí pariwo pé, “Mú eléyìí lọ! Baraba ni kí o dá sílẹ̀ fún wa.”

19. (Baraba ti dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú nígbà kan, ó sì paniyan, ni wọ́n fi sọ ọ́ sẹ́wọ̀n.)

20. Pilatu tún bá wọn sọ̀rọ̀, ó fẹ́ dá Jesu sílẹ̀.

21. Ṣugbọn wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu! Kàn án mọ́ agbelebu!”

22. Ó tún bi wọ́n ní ẹẹkẹta pé, “Kí ni nǹkan burúkú tí ó ṣe? Èmi kò rí ìdí kankan tí ó fi jẹ̀bi ikú. Nígbà tí mo bá ti nà án tán n óo dá a sílẹ̀.”

23. Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ múra kankan, wọ́n ń kígbe pé kí ó kàn án mọ́ agbelebu. Ohùn wọn bá borí.

24. Pilatu bá gbà láti ṣe bí wọ́n ti fẹ́.

Ka pipe ipin Luku 23