6. Ó gbà bẹ́ẹ̀; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ lọ́nà tí ọ̀pọ̀ eniyan kò fi ní mọ̀.
7. Nígbà tí ó di ọjọ́ Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọ́n níláti pa ẹran àsè Ìrékọjá,
8. Jesu rán Peteru ati Johanu, ó ní, “Ẹ lọ ṣe ìtọ́jú ohun tí a óo fi jẹ àsè Ìrékọjá.”
9. Wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á lọ ṣe ètò sí?”
10. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ẹ bá wọ inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín. Ẹ tẹ̀lé e, ẹ bá a wọ inú ilé tí ó bá wọ̀.
11. Kí ẹ sọ fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ni sọ pé níbo ni yàrá ibi tí òun óo ti jẹ àsè Ìrékọjá pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn òun wà?’
12. Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí a ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.”
13. Ni wọ́n bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.
14. Nígbà tí ó tó àkókò oúnjẹ, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn aposteli rẹ̀.
15. Ó sọ fún wọn pé, “Ó ti mú mi lọ́kàn pupọ láti jẹ àsè Ìrékọjá yìí pẹlu yín kí n tó jìyà.
16. Nítorí mo sọ fun yín pé n kò tún ní jẹ ẹ́ mọ́ títí di àkókò tí yóo fi ní ìtumọ̀ tí ó pé ní ìjọba Ọlọrun.”
17. Ó bá mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní, “Ẹ gba èyí, kí ẹ pín in láàrin ara yín.