Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 22:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Satani bá wọ inú Judasi tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.

4. Ó bá lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili láti bá wọn sọ̀rọ̀ bí ọwọ́ wọn yóo ṣe tẹ Jesu.

5. Inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ètò láti fún un ní owó.

6. Ó gbà bẹ́ẹ̀; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ lọ́nà tí ọ̀pọ̀ eniyan kò fi ní mọ̀.

7. Nígbà tí ó di ọjọ́ Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọ́n níláti pa ẹran àsè Ìrékọjá,

8. Jesu rán Peteru ati Johanu, ó ní, “Ẹ lọ ṣe ìtọ́jú ohun tí a óo fi jẹ àsè Ìrékọjá.”

9. Wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á lọ ṣe ètò sí?”

10. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ẹ bá wọ inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín. Ẹ tẹ̀lé e, ẹ bá a wọ inú ilé tí ó bá wọ̀.

11. Kí ẹ sọ fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ni sọ pé níbo ni yàrá ibi tí òun óo ti jẹ àsè Ìrékọjá pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn òun wà?’

12. Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí a ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.”

13. Ni wọ́n bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.

14. Nígbà tí ó tó àkókò oúnjẹ, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn aposteli rẹ̀.

15. Ó sọ fún wọn pé, “Ó ti mú mi lọ́kàn pupọ láti jẹ àsè Ìrékọjá yìí pẹlu yín kí n tó jìyà.

Ka pipe ipin Luku 22