Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 21:3-21 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ó ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, owó ọrẹ talaka opó yìí ju ti gbogbo àwọn yòókù lọ.

4. Nítorí gbogbo àwọn yòókù mú ọrẹ wá ninu ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ní; ṣugbọn òun tí ó jẹ́ aláìní, ó mú gbogbo ohun tí ó fi ẹ̀mí tẹ̀ wá.”

5. Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa Tẹmpili, wọ́n ń sọ nípa àwọn òkúta dáradára tí wọ́n fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ ati ọrẹ tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Jesu bá dáhùn pé,

6. “Ẹ rí gbogbo nǹkan wọnyi, ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí kò ní sí òkúta kan lórí ekeji tí a kò ní wó lulẹ̀.”

7. Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, nígbà wo ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ. Kí ni yóo sì jẹ́ àmì nígbà tí wọn yóo bá fi ṣẹ?”

8. Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí á má ṣe tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo wí pé, ‘Èmi ni Mesaya’ ati pé, ‘Àkókò náà súnmọ́ tòsí.’ Ẹ má tẹ̀lé wọn.

9. Nígbà tí ẹ bá gbúròó ogun ati ìrúkèrúdò, ẹ má jẹ́ kí ó dẹ́rùbà yín. Nítorí dandan ni kí nǹkan wọnyi kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn òpin kò níí tíì dé.”

10. Ó tún fi kún un fún wọn pé “Orílẹ̀-èdè kan yóo máa gbógun ti ekeji, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba kan yóo sì máa gbógun ti ekeji.

11. Ilẹ̀ yóo mì tìtì. Ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo wà ní ibi gbogbo. Ohun ẹ̀rù ati àwọn àmì ńlá yóo hàn lójú ọ̀run.

12. Kí gbogbo èyí tó ṣẹlẹ̀, wọn yóo dojú kọ yín, wọn yóo ṣe inúnibíni si yín. Wọn yóo fà yín lọ sí inú ilé ìpàdé ati sinu ẹ̀wọ̀n. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ọba ati àwọn gomina nítorí orúkọ mi.

13. Anfaani ni èyí yóo jẹ́ fun yín láti jẹ́rìí.

14. Nítorí náà, ẹ má ronú tẹ́lẹ̀ ohun tí ẹ óo sọ láti dáàbò bo ara yín,

15. nítorí èmi fúnra mi ni n óo fi ọ̀rọ̀ si yín lẹ́nu, n óo sì fun yín ní ọgbọ́n tí ó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ninu gbogbo àwọn tí ó lòdì si yín kò ní lè kò yín lójú, tabi kí wọ́n rí ohun wí si yín.

16. Àwọn òbí yín, ati àwọn arakunrin yín, àwọn ẹbí yín, ati àwọn ọ̀rẹ́ yín, yóo kọ̀ yín, wọn yóo sì pa òmíràn ninu yín.

17. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi.

18. Ṣugbọn irun orí yín kankan kò ní ṣègbé.

19. Ẹ óo gba ọkàn yín là nípa ìdúróṣinṣin yín.

20. “Nígbà tí ẹ bá rí i tí ogun yí ìlú Jerusalẹmu ká, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tí yóo di ahoro súnmọ́ tòsí.

21. Nígbà náà kí àwọn tí ó bá wà ní Judia sálọ sórí òkè. Kí àwọn tí ó bá wà ninu ìlú sá kúrò níbẹ̀. Kí àwọn tí ó bá wà ninu abúlé má sá wọ inú ìlú lọ.

Ka pipe ipin Luku 21