Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 21:16-30 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Àwọn òbí yín, ati àwọn arakunrin yín, àwọn ẹbí yín, ati àwọn ọ̀rẹ́ yín, yóo kọ̀ yín, wọn yóo sì pa òmíràn ninu yín.

17. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi.

18. Ṣugbọn irun orí yín kankan kò ní ṣègbé.

19. Ẹ óo gba ọkàn yín là nípa ìdúróṣinṣin yín.

20. “Nígbà tí ẹ bá rí i tí ogun yí ìlú Jerusalẹmu ká, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tí yóo di ahoro súnmọ́ tòsí.

21. Nígbà náà kí àwọn tí ó bá wà ní Judia sálọ sórí òkè. Kí àwọn tí ó bá wà ninu ìlú sá kúrò níbẹ̀. Kí àwọn tí ó bá wà ninu abúlé má sá wọ inú ìlú lọ.

22. Nítorí àkókò ẹ̀san ni àkókò náà, nígbà tí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ yóo ṣẹ.

23. Àwọn obinrin tí ó lóyún ati àwọn tí ó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ gbé! Nítorí ìdààmú pupọ yóo wà ní ayé, ibinu Ọlọrun yóo wà lórí àwọn eniyan yìí.

24. Idà ni a óo fi pa wọ́n. A óo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn tí kì í ṣe Juu yóo wó ìlú Jerusalẹmu palẹ̀, títí àkókò tí a fi fún wọn yóo fi pé.

25. “Àmì yóo yọ ní ojú oòrùn ati ní ojú òṣùpá ati lára àwọn ìràwọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dààmú nígbà tí wọ́n bá gbọ́ tí òkun ń hó, tí ó ń ru sókè.

26. Àwọn eniyan yóo kú sára nítorí ìbẹ̀rù, nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run ni a óo mì tìtì.

27. Nígbà náà ni wọn óo rí Ọmọ-Eniyan tí óo máa bọ̀ ninu ìkùukùu pẹlu agbára ati ògo ńlá.

28. Ẹ jẹ́ kí inú yín kí ó dùn, kí ẹ wá máa yan, nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, nítorí àkókò òmìnira yín ni ó súnmọ́ tòsí.”

29. Ó pa òwe kan fún wọn, ó ní, “Ẹ wo igi ọ̀pọ̀tọ́ ati gbogbo igi yòókù.

30. Nígbà tí ẹ bá rí i, tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn dé.

Ka pipe ipin Luku 21