Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 21:10-24 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ó tún fi kún un fún wọn pé “Orílẹ̀-èdè kan yóo máa gbógun ti ekeji, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba kan yóo sì máa gbógun ti ekeji.

11. Ilẹ̀ yóo mì tìtì. Ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo wà ní ibi gbogbo. Ohun ẹ̀rù ati àwọn àmì ńlá yóo hàn lójú ọ̀run.

12. Kí gbogbo èyí tó ṣẹlẹ̀, wọn yóo dojú kọ yín, wọn yóo ṣe inúnibíni si yín. Wọn yóo fà yín lọ sí inú ilé ìpàdé ati sinu ẹ̀wọ̀n. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ọba ati àwọn gomina nítorí orúkọ mi.

13. Anfaani ni èyí yóo jẹ́ fun yín láti jẹ́rìí.

14. Nítorí náà, ẹ má ronú tẹ́lẹ̀ ohun tí ẹ óo sọ láti dáàbò bo ara yín,

15. nítorí èmi fúnra mi ni n óo fi ọ̀rọ̀ si yín lẹ́nu, n óo sì fun yín ní ọgbọ́n tí ó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ninu gbogbo àwọn tí ó lòdì si yín kò ní lè kò yín lójú, tabi kí wọ́n rí ohun wí si yín.

16. Àwọn òbí yín, ati àwọn arakunrin yín, àwọn ẹbí yín, ati àwọn ọ̀rẹ́ yín, yóo kọ̀ yín, wọn yóo sì pa òmíràn ninu yín.

17. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi.

18. Ṣugbọn irun orí yín kankan kò ní ṣègbé.

19. Ẹ óo gba ọkàn yín là nípa ìdúróṣinṣin yín.

20. “Nígbà tí ẹ bá rí i tí ogun yí ìlú Jerusalẹmu ká, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tí yóo di ahoro súnmọ́ tòsí.

21. Nígbà náà kí àwọn tí ó bá wà ní Judia sálọ sórí òkè. Kí àwọn tí ó bá wà ninu ìlú sá kúrò níbẹ̀. Kí àwọn tí ó bá wà ninu abúlé má sá wọ inú ìlú lọ.

22. Nítorí àkókò ẹ̀san ni àkókò náà, nígbà tí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ yóo ṣẹ.

23. Àwọn obinrin tí ó lóyún ati àwọn tí ó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ gbé! Nítorí ìdààmú pupọ yóo wà ní ayé, ibinu Ọlọrun yóo wà lórí àwọn eniyan yìí.

24. Idà ni a óo fi pa wọ́n. A óo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn tí kì í ṣe Juu yóo wó ìlú Jerusalẹmu palẹ̀, títí àkókò tí a fi fún wọn yóo fi pé.

Ka pipe ipin Luku 21