Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 2:44-52 BIBELI MIMỌ (BM)

44. Wọ́n ṣebí ó wà láàrin ọ̀pọ̀ eniyan tí ń kọ́wọ̀ọ́ rìn ni. Lẹ́yìn tí wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá a kiri láàrin àwọn mọ̀lẹ́bí ati àwọn ojúlùmọ̀ wọn.

45. Nígbà tí wọn kò rí i, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a.

46. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, wọ́n rí i ninu Tẹmpili, ó jókòó láàrin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, òun náà sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.

47. Ẹnu ya gbogbo àwọn tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye rẹ̀ ati nítorí bí ó ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọn ń bi í.

48. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ rí i, ẹnu yà wọ́n. Ìyá rẹ̀ bá bi í pé, “Ọmọ, kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Èmi ati baba rẹ dààmú pupọ nígbà tí à ń wá ọ.”

49. Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá mi kiri? Ẹ kò mọ̀ pé dandan ni fún mi kí n wà ninu ilé Baba mi?”

50. Gbolohun tí ó sọ fún wọn yìí kò sì yé wọn.

51. Ó bá bá wọn lọ sí Nasarẹti, ó sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Ìyá rẹ̀ pa gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi mọ́ ní ọkàn rẹ̀.

52. Bí Jesu ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n rẹ̀ ń pọ̀ sí i, ó sì ń bá ojurere Ọlọrun ati ti àwọn eniyan pàdé.

Ka pipe ipin Luku 2