Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 2:36-37-47 BIBELI MIMỌ (BM)

36-37. Wolii obinrin kan wà tí ń jẹ́ Ana, ọmọ Fanuẹli, ẹ̀yà Aṣeri. Arúgbó kùjọ́kùjọ́ ni. Ọdún meje péré ni ó ṣe ní ilé ọkọ, tí ọkọ rẹ̀ fi kú. Láti ìgbà náà ni ó ti di opó, ó sì tó ẹni ọdún mẹrinlelọgọrin ní àkókò yìí. Kì í fi ìgbà kan kúrò ninu Tẹmpili. Ó ń sìn pẹlu ààwẹ̀ ati ẹ̀bẹ̀ tọ̀sán-tòru.

38. Ní àkókò náà gan-an ni ó dé, ó ń fi ìyìn fún Ọlọrun, ó ń sọ nípa ọmọ yìí fún gbogbo àwọn tí wọn ń retí àkókò ìdásílẹ̀ Jerusalẹmu.

39. Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí gbogbo nǹkan wọnyi tán gẹ́gẹ́ bí òfin Oluwa, wọ́n pada lọ sí Nasarẹti ìlú wọn ní ilẹ̀ Galili.

40. Ọmọ náà ń dàgbà, ó ń lágbára, ó kún fún ọgbọ́n, ojurere Ọlọrun sì wà pẹlu rẹ̀.

41. Àwọn òbí Jesu a máa lọ sí Àjọ̀dún Ìrékọjá ní Jerusalẹmu ní ọdọọdún.

42. Nígbà tí Jesu di ọmọ ọdún mejila, wọ́n lọ sí àjọ yìí gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn.

43. Nígbà tí àjọ̀dún parí, tí wọn ń pada lọ sí ilé, ọmọde náà, Jesu, dúró ní Jerusalẹmu, ṣugbọn àwọn òbí rẹ̀ kò fura.

44. Wọ́n ṣebí ó wà láàrin ọ̀pọ̀ eniyan tí ń kọ́wọ̀ọ́ rìn ni. Lẹ́yìn tí wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá a kiri láàrin àwọn mọ̀lẹ́bí ati àwọn ojúlùmọ̀ wọn.

45. Nígbà tí wọn kò rí i, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a.

46. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, wọ́n rí i ninu Tẹmpili, ó jókòó láàrin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, òun náà sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.

47. Ẹnu ya gbogbo àwọn tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye rẹ̀ ati nítorí bí ó ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọn ń bi í.

Ka pipe ipin Luku 2