Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 19:35-48 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Wọ́n bá fà á lọ sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n tẹ́ ẹ̀wù wọn sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n bá gbé Jesu gùn ún.

36. Bí ó ti ń lọ, wọ́n ń tẹ́ ẹ̀wù wọn sọ́nà.

37. Nígbà tí ó súnmọ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Olifi, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi ayọ̀ kígbe sókè, wọ́n ń yin Ọlọrun nítorí gbogbo ohun ńlá tí wọ́n ti rí.

38. Wọ́n ń wí pé,“Aláásìkí ni ẹni tí ó ń bọ̀ bí ọba ní orúkọ Oluwa.Alaafia ní ọ̀run! Ògo ní òkè ọ̀run!”

39. Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Farisi tí wọ́n wà láàrin àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”

40. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Mò ń sọ fun yín pé, bí àwọn wọnyi bá dákẹ́, àwọn òkúta yóo kígbe sókè.”

41. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ etí ìlú, ó wo ìlú náà, ó bá bú sẹ́kún lórí rẹ̀.

42. Ó ní, “Ìbá ti dára tó lónìí, bí o bá mọ̀ lónìí ohun tí ó jẹ́ ọ̀nà alaafia rẹ! Ṣugbọn ó pamọ́ fún ọ.

43. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn ọ̀tá rẹ yóo gbógun tì ọ́, wọn óo yí ọ ká, wọn yóo há ọ mọ́ yípo.

44. Wọn yóo wó ọ lulẹ̀, wọn yóo sì pa àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ. Wọn kò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ekeji ninu rẹ, nítorí o kò fura nígbà tí Ọlọrun wá bẹ̀ ọ́ wò!”

45. Nígbà tí Jesu wọ inú Tẹmpili, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tajà jáde.

46. Ó sọ fún wọn pè, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!”

47. Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili lojoojumọ. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin, pẹlu àtìlẹ́yìn àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ń wá ọ̀nà láti pa á,

48. ṣugbọn wọn kò rí ọ̀nà, nítorí gbogbo eniyan ń fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Luku 19