Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 19:30-35 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ó wà ní ọ̀kánkán yìí. Nígbà tí ẹ bá wọ ibẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ fà á wá.

31. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ Kí ẹ sọ fún un pé, ‘Oluwa nílò rẹ̀ ni.’ ”

32. Àwọn tí ó rán bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí ó ti sọ fún wọn.

33. Nígbà tí wọn ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn oluwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”

34. Wọ́n sọ fún wọn pé, “Oluwa nílò rẹ̀ ni.”

35. Wọ́n bá fà á lọ sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n tẹ́ ẹ̀wù wọn sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n bá gbé Jesu gùn ún.

Ka pipe ipin Luku 19