Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 19:25-33 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Wọ́n bá dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, ṣebí òun ti ní owó wúrà mẹ́wàá!’

26. Ó wá sọ fún wọn pé, ‘Gbogbo ẹni tí ó bá ní ni a óo tún fún sí i. Ọwọ́ ẹni tí kò sì ní, ni a óo ti gba ìba díẹ̀ tí ó ní!

27. Ní ti àwọn ọ̀tá mi wọnyi, àwọn tí kò fẹ́ kí n jọba, ẹ mú wọn wá síhìn-ín, kí ẹ pa wọ́n lójú mi!’ ”

28. Nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí tán ó tẹ̀síwájú, ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu.

29. Nígbà tí ó súnmọ́ ẹ̀bá Bẹtifage ati Bẹtani, ní apá òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

30. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ó wà ní ọ̀kánkán yìí. Nígbà tí ẹ bá wọ ibẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ fà á wá.

31. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ Kí ẹ sọ fún un pé, ‘Oluwa nílò rẹ̀ ni.’ ”

32. Àwọn tí ó rán bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí ó ti sọ fún wọn.

33. Nígbà tí wọn ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn oluwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”

Ka pipe ipin Luku 19