Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 15:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nígbà tí ó ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ tán, ìyàn wá mú pupọ ní ìlú náà, ebi sì bẹ̀rẹ̀ sí pa á.

15. Ni ó bá lọ ń gbé ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀. Ọmọ-ìbílẹ̀ ìlú yìí ba rán an lọ sí oko rẹ̀ láti máa ṣe ìtọ́jú ẹlẹ́dẹ̀.

16. Ìbá dùn mọ́ ọn láti máa jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kì í fún un ní ohunkohun.

17. Nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní, ‘Àwọn alágbàṣe baba mi tí wọn ń jẹ oúnjẹ ní àjẹṣẹ́kù kò níye. Èmi wá jókòó níhìn-ín, ebi ń pa mí kú lọ!

18. N óo dìde, n óo tọ baba mi lọ. N óo wí fún un pé, “Baba, mo ti ṣẹ Ọlọrun, mo sì ti ṣẹ ìwọ náà.

19. N kò yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ mọ́. Fi mí ṣe ọ̀kan ninu àwọn alágbàṣe rẹ.” ’

20. Ó bá dìde, ó lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀.“Bí ó ti ń bọ̀ ní òkèèrè ni baba rẹ̀ ti rí i. Àánú ṣe é, ó yára, ó dì mọ́ ọn lọ́rùn, ó bá fẹnu kò ó ní ẹnu.

21. Ọmọ náà sọ fún un pé, ‘Baba, mo ti ṣẹ Ọlọrun, mo sì ti ṣẹ ìwọ náà.’

22. Ṣugbọn baba náà sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Ẹ tètè mú aṣọ tí ó dára jùlọ wá, kí ẹ fi wọ̀ ọ́. Ẹ fi òrùka sí i lọ́wọ́, ẹ fún un ní bàtà kí ó wọ̀.

23. Ẹ wá lọ mú mààlúù tí ó sanra wá, kí ẹ pa á, kí ẹ jẹ́ kí á máa ṣe àríyá.

Ka pipe ipin Luku 15