Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 12:35-45 BIBELI MIMỌ (BM)

35. “Ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀, kí ẹ di ara yín ní àmùrè, kí àtùpà yín wà ní títàn.

36. Kí ẹ dàbí àwọn tí ó ń retí oluwa wọn láti pada ti ibi igbeyawo dé. Nígbà tí ó bá dé, tí ó bá kanlẹ̀kùn, lẹsẹkẹsẹ ni wọn yóo ṣí ìlẹ̀kùn fún un.

37. Àwọn ẹrú tí oluwa wọn bá dé, tí ó bá wọn, tí wọn ń ṣọ́nà, ṣe oríire. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo di ara rẹ̀ ní àmùrè, yóo fi wọ́n jókòó lórí tabili, yóo wá gbé oúnjẹ ka iwájú wọn.

38. Bí ó bá dé ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tí ó bá wọn bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe oríire.

39. Kí ẹ mọ èyí pé bí ó bá jẹ́ pé baálé ilé mọ àkókò tí olè yóo dé, kò ní fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ kí olè kó o.

40. Ẹ̀yin náà, ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní àkókò tí ẹ kò nírètí ni Ọmọ-Eniyan yóo dé.”

41. Peteru wá bi Jesu pé, “Oluwa, àwa ni o pa òwe yìí fún tabi fún gbogbo eniyan?”

42. Oluwa sọ pé, “Ta ni olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹni tí oluwa rẹ̀ fi ṣe olórí àwọn iranṣẹ ilé rẹ̀ pé kí ó máa fún wọn ní oúnjẹ lásìkò.

43. Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ṣe oríire tí oluwa rẹ̀ bá bá a tí ó ń ṣe bí wọ́n ti rán an nígbà tí ó bá dé.

44. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé oluwa rẹ̀ yóo fi ṣe ọ̀gá lórí gbogbo nǹkan tí ó ní.

45. Ṣugbọn bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Yóo pẹ́ kí oluwa mi tó dé,’ tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu, tí ó tún ń mutí yó,

Ka pipe ipin Luku 12