Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 11:25-32 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Nígbà tí ó bá dé ibẹ̀, tí ó rí i pé a ti gbá a, a sì ti ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,

26. ẹ̀mí èṣù náà yóo bá lọ mú àwọn ẹ̀mí meje mìíràn wá tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n óo bá wọ ibẹ̀ wọn óo máa gbébẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà á wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.”

27. Bí Jesu ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, obinrin kan láàrin àwọn eniyan fọhùn sókè pé, “Ẹni tí ó bí ọ, tí ó wò ọ́ dàgbà náà ṣe oríire lọpọlọpọ.”

28. Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Èyí tí ó jù ni pé àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń pa á mọ́ ṣe oríire.”

29. Nígbà tí ọ̀pọ̀ eniyan péjọ yí i ká, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran burúkú ni ìran yìí; ó ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fún un àfi àmì Jona.

30. Nítorí bí Jona ti di àmì fún àwọn ará Ninefe, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọmọ-Eniyan yóo jẹ́ àmì fún ìran yìí.

31. Ayaba láti ilẹ̀ gúsù yóo dìde dúró ní ọjọ́ ìdájọ́ láti ko ìran yìí lójú, yóo sì dá wọn lẹ́bi. Nítorí ó wá láti òpin ilẹ̀ ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Solomoni, Ẹ wò ó! Ẹni tí ó ju Solomoni lọ wà níhìn-ín.

32. Àwọn eniyan Ninefe yóo dìde dúró ní ọjọ́ ìdájọ́ láti ko ìran yìí lójú, wọn yóo sì dá wọn lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nígbà tí Jona waasu fún wọn. Ẹ wò ó! Ẹni tí ó ju Jona lọ wà níhìn-ín.

Ka pipe ipin Luku 11