Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 10:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ninu ilé kan náà ni kí ẹ máa gbé. Ohun tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ fun yín ni kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu. Owó iṣẹ́ alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má máa lọ láti ilé dé ilé.

8. Ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀, tí wọn bá gbà yín, ẹ máa jẹ ohun tí wọn bá gbé kalẹ̀ níwájú yín.

9. Ẹ máa wo àwọn aláìsàn sàn. Kí ẹ sọ fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọrun ti dé àrọ́wọ́tó yín.’

10. Ṣugbọn ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀ tí wọn kò bá gbà yín, ẹ jáde lọ sí títì ibẹ̀, kí ẹ sọ pé,

11. ‘Erùpẹ̀ tí ó lẹ̀ mọ́ wa lẹ́sẹ̀ ninu ìlú yín, a gbọ̀n ọ́n kúrò kí ojú lè tì yín. Ṣugbọn kí ẹ mọ èyí pé ìjọba Ọlọrun wà ní àrọ́wọ́tó yín.’

12. Mo sọ fun yín pé yóo sàn fún Sodomu ní ọjọ́ ńlá náà jù fún ìlú náà lọ.

13. “O gbé! Korasini. O gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, wọn ìbá jókòó ninu eérú pẹlu aṣọ ọ̀fọ̀.

14. Yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín lọ.

15. Ìwọ Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o! Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí!

16. “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá kọ̀ yín èmi ni ó kọ̀. Ẹni tí ó bá sì wá kọ̀ mí, ó kọ ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.”

17. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejilelaadọrin pada dé pẹlu ayọ̀. Wọ́n ní, “Oluwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbọ́ràn sí wa lẹ́nu ní orúkọ rẹ.”

Ka pipe ipin Luku 10