Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 9:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ṣebí mo ní òmìnira? Ṣebí aposteli ni mí? Ṣebí mo ti rí Jesu Oluwa wa sójú? Ṣebí àyọrísí iṣẹ́ mi ninu Oluwa ni yín?

2. Bí àwọn ẹlòmíràn kò bá tilẹ̀ gbà mí bí aposteli, ẹ̀yin gbọdọ̀ gbà mí ni, nítorí èdìdì iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ninu Kristi ni ẹ jẹ́.

3. Ìdáhùn mi nìyí fún àwọn tí wọn ń rí wí sí mi.

4. Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹ ati láti mu ni?

5. Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú aya lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wa gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli yòókù ati àwọn arakunrin Oluwa ati Peteru?

6. Àbí èmi ati Banaba nìkan ni a níláti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa?

7. Ta ló jẹ́ ṣe iṣẹ́ ọmọ-ogun tí yóo tún máa bọ́ ara rẹ̀? Ta ló jẹ́ dá oko láì má jẹ ninu èso rẹ̀? Ta ló jẹ́ máa tọ́jú aguntan láìmu ninu wàrà aguntan tí ó ń tọ́jú?

8. Kì í ṣe àpẹẹrẹ ti eniyan nìkan ni mo fi ń sọ nǹkan wọnyi. Ṣebí òfin náà sọ nípa nǹkan wọnyi.

9. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu Òfin Mose pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di ẹnu mààlúù tí o fi ń ṣiṣẹ́ lóko ọkà.” Ǹjẹ́ nítorí mààlúù ni Ọlọrun ṣe sọ èyí?

10. Tabi kò dájú pé nítorí tiwa ni ó ṣe sọ ọ́? Dájúdájú nítorí tiwa ni. Nítorí ó yẹ kí ẹni tí ń roko kí ó máa roko pẹlu ìrètí láti pín ninu ìkórè oko, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ó ń pa ọkà ní ìrètí láti pín ninu ọkà náà.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 9