Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 16:5-20 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Masedonia ni n óo kọ́ gbà kọjá, n óo wá wá sọ́dọ̀ yín.

6. Bóyá n óo dúró lọ́dọ̀ yín, mo tilẹ̀ lè wà lọ́dọ̀ yín ní àkókò òtútù, kí ẹ lè sìn mí lọ sí ibi tí mo bá tún ń lọ.

7. Nítorí pé, nígbà tí mo bá ń kọjá lọ, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé mo kàn fi ojú bà yín lásán ni. Nítorí mo ní ìrètí pé n óo lè dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí Oluwa bá gbà bẹ́ẹ̀.

8. Mo fẹ́ dúró ní Efesu níhìn-ín títí di àjọ̀dún Pẹntikọsti.

9. Nítorí pé mo ní anfaani pupọ láti ṣiṣẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò pọ̀.

10. Bí Timoti bá dé, kí ẹ rí i pé ẹ fi í lára balẹ̀ láàrin yín, nítorí iṣẹ́ Oluwa tí mò ń ṣe ni òun náà ń ṣe.

11. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi àbùkù kàn án. Ẹ ṣe ètò ìrìn àjò fún un ní alaafia, kí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, nítorí èmi ati àwọn arakunrin ń retí rẹ̀.

12. Nípa ti arakunrin wa Apolo, mo gbà á níyànjú gidigidi pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín pẹlu àwọn arakunrin yòókù. Ṣugbọn ó pinnu pé òun kò fẹ́ wá ní àkókò yìí. Ó ń bọ̀ nígbà tí ó bá yá.

13. Ẹ máa ṣọ́nà. Ẹ dúró gbọningbọnin ninu igbagbọ. Ẹ ṣe bí ọkunrin. Ẹ jẹ́ alágbára.

14. Ẹ máa ṣe gbogbo nǹkan tìfẹ́tìfẹ́.

15. Ará, mo ní ẹ̀bẹ̀ kan láti fi siwaju yín. Ẹ mọ̀ pé ìdílé Stefana ni àwọn kinni tí ó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní ilẹ̀ Akaya; ati pé wọ́n ti yan ara wọn láti máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn eniyan Ọlọrun.

16. Mo fẹ́ kí ẹ máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ irú wọn ati gbogbo àwọn tí wọn bá ń bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, tí wọn ń ṣe làálàá níbi iṣẹ́ kan náà.

17. Inú mi dùn nígbà tí Stefana ati Fotunatu ati Akaiku dé, nítorí dídé tí wọ́n dé dí àlàfo tí ó ṣí sílẹ̀ nítorí àìsí yín lọ́dọ̀ wa.

18. Wọ́n mú kí ọkàn mi balẹ̀. Ati ti ẹ̀yin náà. Ẹ máa yẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí.

19. Gbogbo ìjọ tí ó wà ní Esia kí yín. Akuila ati Pirisila ati ìjọ tí ó wà ní ilé wọn ki yín pupọ ninu Oluwa.

20. Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín. Ẹ fi ìfẹnukonu alaafia kí ara yín.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 16