Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 11:14-30 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Mo ṣebí ìṣe ẹ̀dá pàápàá kọ yín pé tí ọkunrin bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn, ó fi àbùkù kan ara rẹ̀;

15. bẹ́ẹ̀ sì ni pé ohun ìyìn ni ó jẹ́ fún obinrin tí ó bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn. Nítorí a fi irun gígùn fún obinrin láti bò ó lórí.

16. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ mọ̀ pé ní tiwa, a kò ní oríṣìí àṣà mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ninu àwọn ìjọ Ọlọrun.

17. Nígbà tí mò ń sọ èyí, nǹkankan wà tí n kò yìn yín fún, nítorí nígbà tí ẹ bá péjọ, ìpéjọpọ̀ yín ń ṣe ibi ju rere lọ.

18. Nítorí, ní ọ̀nà kinni, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ìyapa a máa wà láàrin yín. Mo gbàgbọ́ pé òtítọ́ wà ninu ìròyìn yìí.

19. Nítorí ìyapa níláti wà láàrin yín, kí àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́ láàrin yín lè farahàn.

20. Nítorí èyí, nígbà tí ẹ bá péjọ sí ibìkan náà, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ni ẹ̀ ń jẹ.

21. Nítorí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín níí máa kánjú jẹun, ebi a máa pa àwọn kan nígbà tí àwọn mìíràn ti mu ọtí lámuyó!

22. Ṣé ẹ kò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ, kí ẹ máa mu ni? Àbí ẹ fẹ́ kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọrun ni? Ẹ fẹ́ dójú ti àwọn aláìní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ni kí n sọ fun yín? Ṣé kí n máa yìn yín ni? Rárá o! N kò ní yìn yín fún èyí.

23. Nítorí láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni mo ti gba ohun tí mo fi kọ yín, pé ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi Jesu Oluwa lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ó mú burẹdi,

24. lẹ́yìn tí ó ti dúpẹ́ tán, ó bù ú, ó ní, “Èyí ni ara mi tí ó wà fun yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”

25. Bákan náà ni ó mú ife lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Èyí ni ife ti majẹmu titun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”

26. Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ burẹdi yìí, tí ẹ sì ń mu ninu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Oluwa títí yóo fi dé.

27. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jẹ burẹdi, tabi tí ó ń mu ninu ife Oluwa láìyẹ jẹ̀bi ìlòkulò ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa.

28. Kí olukuluku yẹ ara rẹ̀ wò kí ó tó jẹ ninu burẹdi, kí ó sì tó mu ninu ife Oluwa.

29. Nítorí ẹni tí ó bá ń jẹ, tí ó ń mu láìmọ ìyàtọ̀ tí ó wà ninu ara Kristi, ìdájọ́ ni ó ń jẹ, tí ó sì ń mu, lórí ara rẹ̀.

30. Nítorí èyí ni ọpọlọpọ ninu yín ṣe di aláìlera ati ọlọ́kùnrùn, tí ọpọlọpọ tilẹ̀ ti kú.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 11