Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 6:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. A ti sọ òtítọ́ inú wa fun yín, ẹ̀yin ará Kọrinti. Ọkàn wa ṣípayá si yín.

12. Kò sí ohun kan ní ọkàn wa si yín. Bí ohun kan bá wà, a jẹ́ pé ní ọkàn tiyín ni.

13. Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ. Ohun tí ó yẹ yín ni pé kí ẹ ṣí ọkàn yín payá sí wa.

14. Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìrẹ́pọ̀ wo ni ó wà láàrin ìwà òdodo ati aiṣododo? Tabi, kí ni ó pa ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn pọ̀?

15. Báwo ni Kristi ti ṣe lè fi ohùn ṣọ̀kan pẹlu Èṣù? Kí ni ìbá pa onigbagbọ ati alaigbagbọ pọ̀?

16. Kí ni oriṣa ń wá ninu ilé Ọlọrun? Nítorí ilé Ọlọrun alààyè ni àwa jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ, pé,“N óo máa gbé ààrin wọn,n óo máa káàkiri ní ààrin wọn.N óo jẹ́ Ọlọrun wọn,wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi.

17. Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn,ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí.Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́,kí n lè gbà yín.

18. N óo jẹ́ baba fun yín,ẹ̀yin náà óo sì jẹ́ ọmọ fún mi,lọkunrin ati lobinrin yín.Èmi Oluwa Olodumare ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Kọrinti Keji 6