Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 4:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí èyí, níwọ̀n ìgbà tí ó wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ láti fi iṣẹ́ yìí fún wa ṣe, ọkàn wa kò rẹ̀wẹ̀sì.

2. A ti kọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tíí máa ti eniyan lójú sílẹ̀. A kò hùwà ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ṣugbọn ọ̀nà tí a fi gba iyì ninu ẹ̀rí-ọkàn eniyan ati níwájú Ọlọrun ni pé à ń fi òtítọ́ hàn kedere.

3. Ṣugbọn tí ìyìn rere wa bá ṣókùnkùn, àwọn tí yóo ṣègbé ni ó ṣókùnkùn sí.

4. Àwọn oriṣa ayé yìí ni wọ́n fọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú, tí ọkàn wọn kò fi lè gbàgbọ́. Èyí ni kò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kristi, tí ó lógo, kí ó tàn sí wọn lára; àní, Kristi tíí ṣe àwòrán Ọlọrun.

5. Nítorí kì í ṣe nípa ara wa ni à ń waasu. Ẹni tí à ń waasu rẹ̀ ni Jesu Kristi pé òun ni Oluwa. Iranṣẹ yín ni a jẹ́, nítorí ti Kristi.

6. Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi.

7. Ṣugbọn bí ìkòkò amọ̀ ni àwa tí ìṣúra yìí wà ninu wa rí, kí ó lè hàn gbangba pé Ọlọrun ni ó ní agbára tí ó tóbi jùlọ, kì í ṣe àwa.

Ka pipe ipin Kọrinti Keji 4