Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 12:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ó yẹ kí n fọ́nnu. Rere kan kò ti ibẹ̀ wá, sibẹ n óo sọ ti ìran ati ìfarahàn Oluwa.

2. Mo mọ ọkunrin onigbagbọ kan ní ọdún mẹrinla sẹ́yìn. Bí ó wà ninu ara ni o, bí ó rí ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé ọkunrin yìí lọ sí ọ̀run kẹta.

3-4. Mo mọ ọkunrin yìí, bí ninu ara ni o, bí lójú ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé e lọ sí Paradise níbi tí ó gbé gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe é sọ, ọ̀rọ̀ àṣírí tí kò gbọdọ̀ jáde lẹ́nu eniyan.

5. N óo fọ́nnu nípa irú ọkunrin bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ní fọ́nnu nípa ara tèmi ati nípa àwọn àìlera mi.

6. Bí mo bá fẹ́ fọ́nnu, kò ní jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣiwèrè ni n óo sọ; òtítọ́ ni n óo sọ. Ṣugbọn n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má baà rò nípa mi ju ohun tí ó rí ninu ìwà mi ati ohun tí ó gbọ́ lẹ́nu mi lọ.

7. Nítorí náà, kí n má baà ṣe ìgbéraga nípa àwọn ìfihàn tí ó ga pupọ wọnyi, a fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ẹ̀gún yìí jẹ́ iranṣẹ Satani, láti máa gún mi, kí n má baà gbéraga.

8. Ẹẹmẹta ni mo bẹ Oluwa nítorí rẹ̀ pé kí ó mú un kúrò lára mi.

Ka pipe ipin Kọrinti Keji 12