Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kolose 3:9-21 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ẹ má purọ́ fún ara yín, nígbà tí ẹ ti bọ́ ara àtijọ́ sílẹ̀ pẹlu iṣẹ́ rẹ̀,

10. tí ẹ ti gbé ẹ̀dá titun wọ̀. Èyí ni ẹ̀dá tí ó túbọ̀ ń di titun siwaju ati siwaju gẹ́gẹ́ bí àwòrán ẹni tí ó dá a, tí ó ń mú kí eniyan ní ìmọ̀ Ọlọrun.

11. Ninu ipò titun yìí, kò sí pé ẹnìkan ni Giriki, ẹnìkan ni Juu; tabi pé ẹnìkan kọlà, ẹnìkan kò kọlà, ẹnìkan aláìgbédè, ẹnìkan ẹlẹ́nu òdì, ẹnìkan ẹrú, ẹnìkan òmìnira. Nítorí Kristi ni ohun gbogbo, tí ó wà ninu ohun gbogbo.

12. Nítorí náà, ẹ gbé àánú wọ̀ bí ẹ̀wù, ati inú rere, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ ati sùúrù, bí ó ti yẹ àwọn ẹni tí Ọlọrun yàn, tí wọ́n sì jẹ́ eniyan Ọlọrun ati àyànfẹ́ rẹ̀.

13. Ẹ ní ìfaradà láàrin ara yín. Ẹ máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnìkejì rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti dáríjì yín bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí ara yín.

14. Boríborí gbogbo nǹkan wọnyi, ni pé kí ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀. Ìfẹ́ ni ó so àwọn nǹkan yòókù pọ̀, tí ó sì mú wọn pé.

15. Kí alaafia láti ọ̀dọ̀ Kristi máa ṣe alákòóso ọkàn yín; nítorí Ọlọrun pè yín láti jẹ́ ara kan nítorí alaafia yìí, ẹ sì máa ṣọpẹ́.

16. Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín.

17. Ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ni tabi pé ẹ̀ ń ṣe nǹkankan ni, ẹ máa ṣe é ní orúkọ Oluwa Jesu. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nípasẹ̀ rẹ̀.

18. Ẹ̀yin aya, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ kí onigbagbọ máa ṣe.

19. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín. Ẹ má ṣe kanra mọ́ wọn.

20. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu ninu ohun gbogbo, nítorí ohun tí ó wu Oluwa nìyí.

21. Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe rorò mọ́ àwọn ọmọ yín, kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn má baà bá wọn.

Ka pipe ipin Kolose 3