Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 8:12-25 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

13. Àwọn Farisi sọ fún un pé, “Ò ń jẹ́rìí ara rẹ, ẹ̀rí rẹ kò jámọ́ nǹkankan.”

14. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá ń jẹ́rìí ara mi, sibẹ òtítọ́ ni ẹ̀rí mi, nítorí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn ẹ̀yin kò mọ ibi tí mo ti wá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì mọ ibi tí mò ń lọ.

15. Ojú ni ẹ̀ ń wò tí ẹ fi ń ṣe ìdájọ́, èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.

16. Bí mo bá tilẹ̀ ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni ìdájọ́ mi, nítorí kì í ṣe èmi nìkan ni mò ń ṣe ìdájọ́, èmi ati Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni.

17. Ninu òfin yín a kọ ọ́ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí ẹni meji.

18. Èmi fúnra mi jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi níṣẹ́ náà sì ń jẹ́rìí mi.”

19. Wọ́n bi í pé, “Níbo ni baba rẹ wà?”Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀ mí, ẹ̀ bá mọ Baba mi.”

20. Jesu wí báyìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili ninu iyàrá ìṣúra. Ẹnikẹ́ni kò mú un, nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.

21. Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ ní tèmi; ẹ óo máa wá mi kiri, ẹ óo sì kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.”

22. Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Kò ṣá ní pa ara rẹ̀, nítorí ó wí pé, ‘Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.’ ”

23. Ó wá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin, ní tiyín, ìsàlẹ̀ ni ẹ ti wá, ṣugbọn ní tèmi, òkè ọ̀run ni mo ti wá. Ti ayé yìí ni yín, èmi kì í ṣe ti ayé yìí.

24. Nítorí náà, mo wí fun yín pé ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Nítorí bí ẹ kò bá gbàgbọ́ pé, ‘Èmi ni,’ ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

25. Wọ́n bi í pé, “Ta ni ọ́?”Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ ẹni tí mo jẹ́ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀.

Ka pipe ipin Johanu 8