Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 6:2-11 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ọ̀pọ̀ eniyan ń tẹ̀lé e nítorí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.

3. Jesu bá gun orí òkè lọ, ó jókòó níbẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

4. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, tíí ṣe àjọ̀dún pataki láàrin àwọn Juu.

5. Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá bi Filipi pé, “Níbo ni a ti lè ra oúnjẹ fún àwọn eniyan yìí láti jẹ?”

6. Ó fi èyí wá Filipi lẹ́nu wò ni, nítorí òun fúnrarẹ̀ ti mọ ohun tí òun yóo ṣe.

7. Filipi dá a lóhùn pé, “Burẹdi igba owó fadaka kò tó kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lè fi rí díẹ̀díẹ̀ panu!”

8. Nígbà náà ni Anderu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí ó jẹ́ arakunrin Simoni Peteru sọ fún un pé,

9. “Ọdọmọkunrin kan wà níhìn-ín tí ó ní burẹdi bali marun-un ati ẹja meji, ṣugbọn níbo ni èyí dé láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan yìí?”

10. Jesu ní, “Ẹ ní kí wọ́n jókòó.” Koríko pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan náà bá jókòó. Wọ́n tó bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000).

11. Jesu wá mú burẹdi náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá pín in fún àwọn eniyan tí ó jókòó. Bákan náà ni ó ṣe sí ẹja, ó fún olukuluku bí ó ti ń fẹ́.

Ka pipe ipin Johanu 6