Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 4:35-48 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Ṣé ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìkórè ku oṣù mẹrin.’ Mo sọ fun yín, ẹ gbé ojú yín sókè kí ẹ sì rí i bí oko ti pọ́n fun ìkórè.

36. Ẹni tí ń kórè a máa rí èrè gbà, ó ń kó irè jọ sí ìyè ainipẹkun, kí inú ẹni tí ń fúnrúgbìn ati ti ẹni tí ń kórè lè jọ máa dùn pọ̀.

37. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí pé, ‘Ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ń fúnrúgbìn, ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ń kórè.’

38. Mo ran yín láti kórè níbi tí ẹ kò ti ṣiṣẹ́ ọ̀gbìn. Àwọn ẹnìkan ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin wá ń jèrè iṣẹ́ wọn.”

39. Ọpọlọpọ ninu àwọn ará Samaria tí ó wá láti inú ìlú gbà á gbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ obinrin tí ó jẹ́rìí pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi.”

40. Nígbà tí àwọn ará Samaria dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn. Ó bá dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meji.

41. Ọpọlọpọ àwọn mìíràn tún gbàgbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

42. Wọ́n wí fún obinrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ohun tí o sọ ni a fi gbàgbọ́, nítorí àwa fúnra wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, a wá mọ̀ nítòótọ́ pé òun ni Olùgbàlà aráyé.”

43. Lẹ́yìn ọjọ́ meji, Jesu jáde kúrò níbẹ̀ lọ sí Galili.

44. Nítorí òun fúnrarẹ̀ jẹ́rìí pé, “Wolii kan kò ní ọlá ninu ìlú baba rẹ̀.”

45. Nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, nítorí pé àwọn náà lọ sí ibi àjọ̀dún náà.

46. Jesu tún lọ sí ìlú Kana ti Galili níbi tí ó ti sọ omi di ọtí ní ìjelòó. Ìjòyè kan wà ní Kapanaumu tí ọmọ rẹ̀ ń ṣàìsàn.

47. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti dé sí Galili láti Judia, ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá wo ọmọ òun sàn, nítorí ọmọ ọ̀hún ń kú lọ.

48. Jesu wí fún un pé, “Bí ẹ kò bá rí iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu ẹ kò ní gbàgbọ́.”

Ka pipe ipin Johanu 4