Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 4:17-35 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Obinrin náà dáhùn pé, “Èmi kò ní ọkọ.”Jesu wí fún un pé, “O wí ire pé o kò ní ọkọ,

18. nítorí o ti ní ọkọ marun-un rí, ẹni tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nisinsinyii kì í sì í ṣe ọkọ rẹ. Òtítọ́ ni o sọ.”

19. Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé wolii ni ọ́.

20. Ní orí òkè tí ó wà lọ́hùn-ún yìí ni àwọn baba wa ń sin Ọlọrun, ṣugbọn ẹ̀yin wí pé Jerusalẹmu ni ibi tí a níláti máa sìn ín.”

21. Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, gbà mí gbọ́! Àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé, ati ní orí òkè yìí ni, ati ní Jerusalẹmu ni, kò ní sí ibi tí ẹ óo ti máa sin Baba mọ́.

22. Ẹ̀yin ará Samaria kò mọ ẹni tí ẹ̀ ń sìn. Àwa Juu mọ ẹni tí à ń sìn, nítorí láti ọ̀dọ̀ wa ni ìgbàlà ti wá.

23. Ṣugbọn àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, nígbà tí àwọn tí ń jọ́sìn tòótọ́ yóo máa sin Baba ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́, nítorí irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá kí wọ́n máa sin òun.

24. Ẹ̀mí ni Ọlọrun, àwọn tí ó bá ń sìn ín níláti sìn ín ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́.”

25. Obinrin náà sọ fún un pé, “Mo mọ̀ pé Mesaya, tí ó ń jẹ́ Kristi, ń bọ̀. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi ohun gbogbo hàn wá.”

26. Jesu wí fún un pé, “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Mesaya náà.”

27. Ní àkókò yìí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé. Ẹnu yà wọ́n pé obinrin ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni ninu wọn kò bi obinrin náà pé kí ni ó ń wá? Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò bi òun náà pé kí ló dé tí ó fi ń bá obinrin sọ̀rọ̀?

28. Obinrin náà fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sí ààrin ìlú, ó sọ fún àwọn eniyan pé,

29. “Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?”

30. Wọ́n bá jáde láti inú ìlú lọ sọ́dọ̀ Jesu.

31. Lẹ́yìn tí obinrin náà ti lọ sí ààrin ìlú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Rabi, jẹun.”

32. Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ní oúnjẹ láti jẹ tí ẹ̀yin kò mọ̀ nípa rẹ̀.”

33. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè láàrin ara wọn pé, “Àbí ẹnìkan ti gbé oúnjẹ wá fún un ni?”

34. Jesu wí fún wọn pé, “Ní tèmi, oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ati láti parí iṣẹ́ tí ó fún mi ṣe.

35. Ṣé ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìkórè ku oṣù mẹrin.’ Mo sọ fun yín, ẹ gbé ojú yín sókè kí ẹ sì rí i bí oko ti pọ́n fun ìkórè.

Ka pipe ipin Johanu 4