Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 20:27-31 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ó wá wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá, wo ọwọ́ mi, mú ọwọ́ rẹ wá kí o fi kan ẹ̀gbẹ́ mi. Má ṣe alaigbagbọ mọ́, ṣugbọn gbàgbọ́.”

28. Tomasi dá a lóhùn pé, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!”

29. Jesu wí fún un pé, “O wá gbàgbọ́ nítorí o rí mi! Àwọn tí ó gbàgbọ́ láì rí mi ṣe oríire!”

30. Ọpọlọpọ nǹkan ati iṣẹ́ abàmì mìíràn ni Jesu ṣe lójú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí a kò kọ sinu ìwé yìí.

31. Ṣugbọn a kọ ìwọ̀nyí kí ẹ lè gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun, ati pé tí ẹ bá gbàgbọ́, kí ẹ lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Johanu 20