Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 19:28-42 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jesu mọ̀ pé ohun gbogbo ti parí, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ, ó ní, “Òùngbẹ ń gbẹ mí.”

29. Àwo ọtí kan wà níbẹ̀. Wọ́n bá fi kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí náà, wọ́n fi sórí ọ̀pá gígùn kan, wọ́n nà án sí i lẹ́nu.

30. Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!”Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́.

31. Nítorí ọjọ́ náà jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ̀dún Ìrékọjá, kí òkú má baà wà lórí agbelebu ní Ọjọ́ Ìsinmi, àwọn Juu bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí wọ́n dá àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ní ojúgun, kí wọ́n gbé wọn kúrò lórí agbelebu nítorí pé Ọjọ́ Ìsinmi pataki ni Ọjọ́ Ìsinmi náà.

32. Àwọn ọmọ-ogun bá lọ, wọ́n dá ekinni-keji àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu Jesu lójúgun.

33. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n rí i pé ó ti kú, nítorí náà wọn kò dá a lójúgun.

34. Ṣugbọn ọmọ-ogun kan fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, ẹ̀jẹ̀ ati omi bá tú jáde.

35. (Ẹni tí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ojú rẹ̀ ni ó jẹ́rìí, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀, ó mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́.)

36. Gbogbo èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Kò sí egungun rẹ̀ kan tí wọ́n ṣẹ́.”

37. Ìwé Mímọ́ tún wí níbòmíràn pé, “Wọn yóo wo ẹni tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ gún.”

38. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, Josẹfu ará Arimatia bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí òun gbé òkú Jesu lọ. Josẹfu yìí jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó fara pamọ́ nítorí ó bẹ̀rù àwọn Juu. Pilatu bá fún un ní àṣẹ láti gbé òkú Jesu. Ó bá lọ gbé e.

39. Nikodemu, tí ó fòru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan rí, mú àdàlú òróró olóòórùn dídùn olówó iyebíye oríṣìí meji wá, wíwúwo rẹ̀ tó ọgbọ̀n kilogiramu.

40. Wọ́n fi òróró yìí tọ́jú òkú Jesu, wọ́n bá wé e ní aṣọ-ọ̀gbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà ìsìnkú àwọn Juu.

41. Ọgbà kan wà níbi tí wọ́n ti kan Jesu mọ́ agbelebu. Ibojì titun kán wà ninu ọgbà náà, wọn kò ì tíì sin òkú kankan sinu rẹ̀ rí.

42. Wọ́n tẹ́ òkú Jesu sibẹ, nítorí ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn Juu ni, ati pé ibojì náà súnmọ́ tòsí.

Ka pipe ipin Johanu 19