Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 18:4-18 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”

5. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.”Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn.

6. Nígbà tí ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀.

7. Ó tún bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”Wọ́n dáhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”

8. Jesu wí fún wọn pé, “Mo sọ fun yín pé èmi gan-an nìyí. Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọnyi máa lọ.”

9. (Kí ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Ọ̀kan kan kò ṣègbé ninu àwọn tí o ti fi fún mi.”)

10. Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ó ní idà kan fà á yọ, ó bá ṣá ẹrú Olórí Alufaa, ó gé e létí ọ̀tún. Maliku ni orúkọ ẹrú náà.

11. Jesu bá sọ fún Peteru pé, “Ti idà rẹ bọ inú àkọ̀. Àbí kí n má jẹ ìrora ńlá tí Baba ti yàn fún mi ni?”

12. Ni àwọn ọmọ-ogun ati ọ̀gágun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn Juu bá mú Jesu, wọ́n dè é,

13. wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Anasi tíí ṣe baba iyawo Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà.

14. Kayafa yìí ni ó fi ìmọ̀ràn fún àwọn Juu pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún gbogbo eniyan.

15. Ṣugbọn Simoni Peteru ń tẹ̀lé Jesu pẹlu ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn. Ọmọ-ẹ̀yìn keji yìí jẹ́ ẹni tí Olórí Alufaa mọ̀.

16. Ṣugbọn Peteru dúró lóde lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn keji tí Olórí Alufaa mọ̀ jáde, ó bá mú Peteru wọ agbo-ilé.

17. Nígbà náà ni ọmọge tí ó ń ṣọ́nà sọ fún Peteru pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkunrin yìí ni ọ́?”Peteru dáhùn pé, “Rárá o!”

18. Àwọn ẹrú ati àwọn ẹ̀ṣọ́ jọ dúró ní àgbàlá, wọ́n ń yáná tí wọ́n fi èédú dá, nítorí òtútù mú. Peteru náà dúró lọ́dọ̀ wọn, òun náà ń yáná.

Ka pipe ipin Johanu 18