Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 11:22-42 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ṣugbọn nisinsinyii náà, mo mọ̀ pé ohunkohun tí o bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo ṣe é fún ọ.”

23. Jesu wí fún un pé, “Arakunrin rẹ yóo jí dìde.”

24. Mata dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé yóo jí dìde ní ajinde ọjọ́ ìkẹyìn.”

25. Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ajinde ati ìyè. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, sibẹ yóo yè.

26. Gbogbo ẹni tí ó bá wà láàyè, tí ó bá gbà mí gbọ́, kò ní kú laelae. Ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́?”

27. Ó dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, mo gbàgbọ́ pé ìwọ ni Mesaya Ọmọ Ọlọrun tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.”

28. Nígbà tí Mata ti sọ báyìí tán, ó lọ pe Maria arabinrin rẹ̀ sí ìkọ̀kọ̀. Ó ní, “Olùkọ́ni ti dé, ó ń pè ọ́.”

29. Bí Maria ti gbọ́, ó dìde kíá, ó bá lọ sọ́dọ̀ Jesu.

30. (Jesu kò tíì wọ ìlú, ó wà ní ibi tí Mata ti pàdé rẹ̀.)

31. Nígbà tí àwọn Juu tí ó wà ninu ilé pẹlu Maria, tí wọn ń tù ú ninu, rí i pé ó sáré dìde, ó jáde, àwọn náà tẹ̀lé e, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti lọ sunkún ni.

32. Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.”

33. Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́.

34. Ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?”Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wá wò ó.”

35. Ni Jesu bá bú sẹ́kún.

36. Nígbà náà ni àwọn Juu sọ pé, “Ẹ ò rí i bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”

37. Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?”

38. Orí Jesu tún wú, ó bá lọ síbi ibojì. Ninu ihò òkúta ni ibojì náà wà, òkúta sì wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀.

39. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.”Mata, arabinrin ẹni tí ó kú, sọ fún un pé, “Oluwa, ó ti ń rùn, nítorí ó ti di òkú ọjọ́ mẹrin!”

40. Jesu wí fún un pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé bí o bá gbàgbọ́ ìwọ yóo rí ògo Ọlọrun.”

41. Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi.

42. Mo mọ̀ pé nígbà gbogbo ni ò ń gbọ́ tèmi, ṣugbọn nítorí ti àwọn eniyan tí ó dúró yíká ni mo ṣe sọ èyí kí wọ́n lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni o rán mi níṣẹ́.”

Ka pipe ipin Johanu 11