Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 1:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé, ni Ọ̀rọ̀ ti wà, Ọ̀rọ̀ wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun sì ni Ọ̀rọ̀ náà.

2. Òun ni ó wà pẹlu Ọlọrun ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé.

3. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, ninu gbogbo ohun tí a dá, kò sí ohun kan tí a dá lẹ́yìn rẹ̀.

4. Òun ni orísun ìyè, ìyè náà ni ìmọ́lẹ̀ aráyé.

5. Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn kò sì lè borí rẹ̀.

6. Ọkunrin kan wà tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johanu.

Ka pipe ipin Johanu 1