Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jakọbu 5:14-20 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ń ṣàìsàn, kí ó pe àwọn àgbà ìjọ jọ, kí wọ́n gbadura fún un, kí wọ́n fi òróró pa á lára ní orúkọ Oluwa.

15. Adura pẹlu igbagbọ yóo mú kí ara aláìsàn náà yá. Oluwa yóo gbé e dìde, a óo sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá jì í.

16. Ẹ máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, ẹ máa gbadura fún ara yín kí ẹ lè ní ìwòsàn. Adura àtọkànwá olódodo lágbára, nítorí Ọlọrun a máa fi àṣẹ sí i.

17. Eniyan ẹlẹ́ran-ara bí àwa ni Elija. Ó fi tọkàntọkàn gbadura pé kí òjò má rọ̀. Òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún odidi ọdún mẹta ati oṣù mẹfa.

18. Ó tún gbadura, òjò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ láti òkè, ilẹ̀ sì hu ohun ọ̀gbìn jáde.

19. Ẹ̀yin ará mi, bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí ẹnìkan bá tọ́ ọ sọ́nà,

20. ẹ mọ̀ dájú pé ẹni tí ó bá mú ẹlẹ́ṣẹ̀ pada kúrò ninu ìṣìnà rẹ̀ gba ọkàn ẹni náà lọ́wọ́ ikú, ó sì mú kí ìgbàgbé bá ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Jakọbu 5