Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jakọbu 2:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ará mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní igbagbọ ninu Oluwa wa, Jesu Kristi, Oluwa tí ó lógo, ẹ má máa ṣe ojuṣaaju.

2. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá wọ àwùjọ yín, tí ó fi òrùka wúrà sọ́wọ́, tí ó wọ aṣọ tí ń dán, tí talaka kan náà bá wọlé tí ó wọ aṣọ tí ó dọ̀tí;

3. ẹ óo máa fi ojurere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídán, ẹ óo sọ fún un pé, “Wá jókòó níbi dáradára yìí.” Ṣugbọn ẹ óo wá sọ fún talaka pé, “Dúró níbẹ̀, tabi wá jókòó nílẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ mi níhìn-ín.”

4. Ǹjẹ́ ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin ara yín, ǹjẹ́ ẹ kò sì máa ṣe ìdájọ́ pẹlu èrò burúkú.

5. Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Ọlọrun ti yan àwọn mẹ̀kúnnù ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu igbagbọ ati láti jogún ìjọba tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀.

Ka pipe ipin Jakọbu 2