Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jakọbu 1:15-27 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá lóyún, á bí ẹ̀ṣẹ̀; nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bá gbilẹ̀ tán á bí ikú.

16. Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ má tan ara yín jẹ.

17. Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀.

18. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa, kí á lè jẹ́ àkọ́kọ́ ninu àwọn ẹ̀dá rẹ̀.

19. Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo fẹ́ kí ẹ mọ nǹkankan: eniyan níláti tètè gbọ́ ọ̀rọ̀, ṣugbọn kí ó lọ́ra láti désì pada, kí ó sì lọ́ra láti bínú.

20. Nítorí ibinu eniyan kì í yọrí sí ire tí Ọlọrun fẹ́.

21. Nítorí náà, ẹ mú gbogbo ìwà èérí ati gbogbo ìwàkiwà à-ń-wá-ipò-aṣaaju kúrò, kí á lè wà ní ipò kinni. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sinu yín, tí ó lè gba ọkàn yín là.

22. Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyìn rere ṣe ìwà hù; ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán. Bí ẹ bá ń gbọ́ lásán, ara yín ni ẹ̀ ń tàn jẹ.

23. Nítorí bí eniyan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò fi ṣe ìwà hù, olúwarẹ̀ dàbí ẹni tí ó wo ojú ara rẹ̀ ninu dígí.

24. Ó wo ara rẹ̀ dáradára, ó kúrò níbẹ̀, kíá ó ti gbàgbé bí ojú rẹ̀ ti rí.

25. Ṣugbọn ẹni tí ó bá wo òfin tí ó pé, tíí ṣe orísun òmìnira, tí ó sì dúró lé e lórí, olúwarẹ̀ kì í ṣe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó gbàgbé rẹ̀, ṣugbọn ó ń fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ìwà hù. Olúwarẹ̀ di ẹni ibukun nítorí ó ń fi ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ ṣe ìwà hù.

26. Bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ olùfọkànsìn, tí kò bá kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni, asán sì ni ẹ̀sìn rẹ̀.

27. Ẹ̀sìn tí ó pé, tí kò lábàwọ́n níwájú Ọlọrun Baba ni pé kí eniyan máa ran àwọn ọmọ tí kò ní òbí ati àwọn opó lọ́wọ́ ninu ipò ìbànújẹ́ wọn, kí eniyan sì pa ara rẹ̀ mọ́ láìléèérí ninu ayé.

Ka pipe ipin Jakọbu 1