Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 8:5-9 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Angẹli náà bá mú àwo turari yìí, ó bu iná láti orí pẹpẹ ìrúbọ kún inú rẹ̀, ó bá jù ú sí orí ilẹ̀ ayé. Ààrá bá bẹ̀rẹ̀ sí sán, mànàmáná ń kọ, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì.

6. Àwọn angẹli meje tí wọ́n mú kàkàkí meje lọ́wọ́ bá múra láti fun kàkàkí wọn.

7. Ekinni fun kàkàkí rẹ̀. Ni yìnyín ati iná pẹlu ẹ̀jẹ̀ bá tú dà sórí ilẹ̀ ayé. Ìdámẹ́ta ayé bá jóná, ati ìdámẹ́ta àwọn igi ati gbogbo koríko tútù.

8. Angẹli keji fun kàkàkí rẹ̀. Ni a bá ju nǹkankan tí ó dàbí òkè gíga tí ó ń jóná sinu òkun. Ó bá sọ ìdámẹ́ta òkun di ẹ̀jẹ̀.

9. Ìdámẹ́ta gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun ni wọ́n kú. Ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ ojú òkun ni wọ́n sì fọ́ túútúú.

Ka pipe ipin Ìfihàn 8