Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 9:40-43 BIBELI MIMỌ (BM)

40. Peteru bá ti gbogbo wọn jáde, ó kúnlẹ̀, ó gbadura. Ó bá kọjú sí òkú náà, ó ní, “Tabita, dìde.” Ni Tabita bá lajú, ó rí Peteru, ó bá dìde jókòó.

41. Peteru bá fà á lọ́wọ́ dìde. Ó pe àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn opó, ó bá fa Dọkasi lé wọn lọ́wọ́ láàyè.

42. Ìròyìn yìí tàn ká gbogbo Jọpa, ọpọlọpọ sì gba Oluwa gbọ́.

43. Peteru dúró fún ọjọ́ pupọ ní Jọpa, ní ọ̀dọ̀ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 9