Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 9:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Oluwa sọ fún un pé, “Lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí mo ti yàn án láti mú orúkọ mi lọ siwaju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati àwọn ọba wọn ati àwọn ọmọ Israẹli.

16. N óo fi oríṣìíríṣìí ìyà tí ó níláti jẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”

17. Anania bá lọ, ó wọ inú ilé náà, ó fi ọwọ́ kan Saulu. Ó ní, “Saulu arakunrin mi, Oluwa ni ó rán mi sí ọ. Jesu tí ó farahàn ọ́ ní ojú ọ̀nà tí o gbà wá, ni ó rán mi wá, kí o lè tún ríran, kí o sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.”

18. Lẹsẹkẹsẹ nǹkankan bọ́ sílẹ̀ lójú rẹ̀ bí ìpẹ́pẹ́, ó sì tún ríran. Ó dìde, ó bá gba ìrìbọmi.

19. Ó bá jẹun, ara rẹ̀ bá tún mókun. Ó wà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó wà ní Damasku fún ọjọ́ díẹ̀.

20. Láì jáfara ó bẹ̀rẹ̀ sí waasu ninu ilé ìpàdé àwọn Juu pé Jesu ni Ọmọ Ọlọrun.

21. Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n ní “Ará ibí yìí kọ́ ni ó ń pa àwọn tí ó ń pe orúkọ yìí ní Jerusalẹmu, tí ó tún wá síhìn-ín láti fi ẹ̀wọ̀n dè wọ́n, tí ó fẹ́ fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa?”

22. Ṣugbọn ńṣe ni Saulu túbọ̀ ń lágbára sí i. Àwọn Juu tí ó ń gbé Damasku kò mọ ohun tí wọ́n le wí mọ́, nítorí ó fi ẹ̀rí hàn pé Jesu ni Mesaya.

23. Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 9