Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 8:31-36 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Ó dáhùn pé, “Ó ṣe lè yé mi láìjẹ́ pé ẹnìkan bá ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi?” Ó bá bẹ Filipi pé kí ó gòkè wọ inú ọkọ̀, kí ó jókòó ti òun.

32. Apá ibi tí ó ń kà nìyí:“Bí aguntan tí a mú lọ sí ilé ìpẹran,tí à ń fà níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ya ẹnu rẹ̀.

33. A rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. A kò ṣe ẹ̀tọ́ nípa ọ̀ràn rẹ̀.Ẹnikẹ́ni kò ní lè sọ nípa ìran rẹ̀.Nítorí a pa á run kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.”

34. Ìwẹ̀fà náà sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ ta ni wolii Ọlọrun yìí ń sọ, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ni tabi ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn?”

35. Filipi bá tẹnu bọ ọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọsílẹ̀ yìí, ó waasu ìyìn rere Jesu fún un.

36. Bí wọn tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé odò kan. Ìwẹ̀fà náà sọ pé, “Wo omi. Kí ló dé tí o ò fi kúkú rì mí bọmi?” [

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 8