Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 8:21-34 BIBELI MIMỌ (BM)

21. O kò ní ipa tabi ìpín ninu ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ọkàn rẹ kò tọ́ níwájú Ọlọrun.

22. Nítorí náà, ronupiwada kúrò ninu ohun burúkú yìí, kí o tún bẹ Oluwa kí ó dárí èrò ọkàn rẹ yìí jì ọ́.

23. Nítorí mo wòye pé ẹ̀tanú ti gbà ọ́ lọ́kàn, àtipé aiṣododo ti dè ọ́ lẹ́wọ̀n.”

24. Simoni dá Peteru lóhùn pé, “Ẹ gbadura sí Oluwa fún mi kí ohunkohun tí ẹ wí má ṣẹlẹ̀ sí mi.”

25. Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti jẹ́rìí tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Oluwa tán, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń waasu ìyìn rere ní ọpọlọpọ àwọn abúlé ilẹ̀ Samaria bí wọ́n ti ń pada lọ.

26. Angẹli Oluwa sọ fún Filipi pé, “Dìde kí o lọ sí apá gúsù, ní ọ̀nà tí ó lọ láti Jerusalẹmu sí Gasa.” (Aṣálẹ̀ ni ọ̀nà yìí gbà lọ.)

27. Ni Filipi bá dìde lọ. Ó bá rí ọkunrin ará Etiopia kan. Ó jẹ́ ìwẹ̀fà onípò gíga kan lábẹ́ Kandake, ọbabinrin Etiopia. Òun ni akápò ìjọba. Ó ti lọ ṣe ìsìn ní Jerusalẹmu,

28. ó wá ń pada lọ sílé. Ó jókòó ninu ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó ń ka ìwé wolii Aisaya.

29. Ẹ̀mí sọ fún Filipi pé, “Lọ síbi ọkọ nnì kí o súnmọ́ ọn.”

30. Nígbà tí Filipi sáré, tí ó súnmọ́ ọn, ó gbọ́ tí ó ń ka ìwé wolii Aisaya. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ohun tí ò ń kà yé ọ?”

31. Ó dáhùn pé, “Ó ṣe lè yé mi láìjẹ́ pé ẹnìkan bá ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi?” Ó bá bẹ Filipi pé kí ó gòkè wọ inú ọkọ̀, kí ó jókòó ti òun.

32. Apá ibi tí ó ń kà nìyí:“Bí aguntan tí a mú lọ sí ilé ìpẹran,tí à ń fà níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ya ẹnu rẹ̀.

33. A rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. A kò ṣe ẹ̀tọ́ nípa ọ̀ràn rẹ̀.Ẹnikẹ́ni kò ní lè sọ nípa ìran rẹ̀.Nítorí a pa á run kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.”

34. Ìwẹ̀fà náà sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ ta ni wolii Ọlọrun yìí ń sọ, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ni tabi ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn?”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 8