Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 7:40-56 BIBELI MIMỌ (BM)

40. Wọ́n sọ fún Aaroni pé, ‘Ṣe oriṣa fún wa kí á rí ohun máa bọ, kí ó máa tọ́ wa sí ọ̀nà. A kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti.’

41. Wọ́n bá ṣe ère ọmọ mààlúù kan ní àkókò náà, wọ́n rúbọ sí i. Wọ́n bá ń ṣe àríyá lórí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.

42. Ọlọrun bá pada lẹ́yìn wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ láti máa sin ìràwọ̀ ojú ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé,‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli,ǹjẹ́ ẹ mú ẹran wá fi rúbọ sí mi fún ogoji ọdún ní aṣálẹ̀?

43. Ṣebí àtíbàbà Moleki ni ẹ gbé rù,ati ìràwọ̀ Refani oriṣa yín,àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa foríbalẹ̀ fún?N óo le yín lọ sí ìgbèkùn, ẹ óo kọjá Babiloni.’

44. “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí kan ní aṣálẹ̀. Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó ṣe àgọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí òun ti fihàn án tẹ́lẹ̀.

45. Àwọn baba wa tí wọ́n tẹ̀lé Joṣua gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun lé kúrò níwájú wọn, lẹ́yìn náà wọ́n gbé àgọ́ náà wá. Àgọ́ yìí sì wà pẹlu wa títí di àkókò Dafidi.

46. Dafidi bá ojurere Ọlọrun pàdé; ó wá bèèrè pé kí Ọlọrun jẹ́ kí òun kọ́ ilé fún òun, Ọlọrun Jakọbu.

47. Ṣugbọn Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.

48. “Bẹ́ẹ̀ ni Ọba tí ó ga jùlọ kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́. Gẹ́gẹ́ bí wolii nì ti sọ:

49. ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni tìmùtìmù ìtìsẹ̀ mi.Irú ilé wo ni ẹ̀ báà kọ́ fún mi?Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí.Níbo ni ẹ̀ báà palẹ̀ mọ́ fún mi pé kí n ti máa sinmi?

50. Ṣebí èmi ni mo fọwọ́ mi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi?’

51. “Ẹ̀yin olóríkunkun, ọlọ́kàn líle, elétí dídi wọnyi! Nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń tako Ẹ̀mí Mímọ́. Bí àwọn baba yín ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà rí.

52. Èwo ninu àwọn wolii ni àwọn Baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọ́n pa àwọn tí wọ́n sọtẹ́lẹ̀ pé Ẹni olódodo yóo dé. Ní àkókò yìí ẹ wá dìtẹ̀ sí i, ẹ ṣe ikú pa á.

53. Ẹ̀yin yìí ni ẹ gba òfin Ọlọrun láti ọwọ́ àwọn angẹli, ṣugbọn ẹ kò pa òfin náà mọ́.”

54. Nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó gún wọn lọ́kàn. Wọ́n bá pòṣé sí i.

55. Ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ gbé Stefanu, ó tẹ ojú mọ́ òkè ọ̀run, ó rí ògo Ọlọrun, ó tún rí Jesu tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun.

56. Ó bá dáhùn pé, “Ẹ wò ó, mo rí ojú ọ̀run tí ó pínyà. Mo wá rí Ọmọ-Eniyan tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 7