Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 28:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi, wọ́n fẹ́ dá mi sílẹ̀ nítorí wọn kò rí ohunkohun tí mo ṣe tí wọ́n fi lè dá mi lẹ́bi ikú.

19. Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu kò gbà pé kí wọ́n dá mi sílẹ̀, kò sí ohun tí mo tún lè ṣe jù pé kí n gbé ẹjọ́ mi wá siwaju Kesari lọ. Kì í ṣe pé mo ní ẹjọ́ kankan láti bá orílẹ̀-èdè wa rò.

20. Ìdí nìyí tí mo fi ranṣẹ pè yín láti ri yín kí n sì ba yín sọ̀rọ̀; nítorí ohun tí Israẹli ń retí ni wọ́n ṣe fi ẹ̀wọ̀n so mí báyìí.”

21. Wọ́n dá a lóhùn pé, “A kò rí ìwé gbà nípa rẹ láti Judia; bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni ninu àwọn ará wa kò débí láti ròyìn rẹ tabi láti sọ̀rọ̀ rẹ ní ibi.

22. A rò pé ó dára kí á gbọ́ ohun tí o ní lọ́kàn, nítorí pé ó ti dé etígbọ̀ọ́ wa pé níbi gbogbo ni àwọn eniyan lòdì sí ẹgbẹ́ tí ó yàtọ̀ yìí.”

23. Wọ́n bá dá ọjọ́ tí wọn yóo wá fún un. Nígbà tí ọjọ́ pé, pupọ ninu wọn wá kí i. Ó bá dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀, ó ń fi tẹ̀dùntẹ̀dùn ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun fún wọn, ó sì ń fi ẹ̀rí tí ó wà ninu ìwé Òfin Mose ati ìwé wolii nípa Jesu hàn wọ́n láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.

24. Àwọn mìíràn gba ohun tí ó sọ gbọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn kò gbàgbọ́.

25. Nígbà tí ohùn wọn kò dọ́gba láàrin ara wọn, wọ́n bá ń túká lọ. Paulu wá tún sọ gbolohun kan, ó ní, “Òtítọ́ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sọ láti ẹnu wolii Aisaya sí àwọn baba-ńlá yín.

26. Ó ní,‘Lọ sọ fún àwọn eniyan yìí pé:Ẹ óo fetí yín gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín;Ẹ óo wò ó títí, ṣugbọn ẹ kò ní mọ̀ ọ́n.

27. Nítorí ọkàn àwọn eniyan yìí kò ṣí; wọ́n ti di alágbọ̀ọ́ya,wọ́n ti dijú.Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀,wọn ìbá fi ojú wọn ríran,wọn ìbá fetí gbọ́ràn,òye ìbá yé wọn,wọn ìbá yipada;èmi ìbá sì wò wọ́n sàn.’

28. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a ti rán iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọrun yìí sí àwọn tí kì í ṣe Juu. Àwọn ní tiwọn yóo gbọ́.”

29. Nígbà tí Paulu ti sọ báyìí tán, àwọn Juu túká, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn kíkankíkan.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 28