Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 26:23-32 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Èyí ni pé Mesaya níláti jìyà; àtipé òun ni yóo kọ́ jí dìde kúrò ninu òkú tí yóo sì kéde iṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu.”

24. Bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀ báyìí, Fẹstu ké mọ́ ọn pé, “Paulu, orí rẹ dàrú! Ìwé àmọ̀jù ti dà ọ́ lórí rú.”

25. Paulu dáhùn ó ní, “Fẹstu ọlọ́lá, orí mi kò dàrú. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ gan-an ni mò ń sọ.

26. Gbogbo nǹkan wọnyi yé Kabiyesi, nítorí náà ni mo ṣe ń sọ ọ́ láìfòyà. Ó dá mi lójú pé kò sí ohun tí ó pamọ́ fún un ninu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kì í ṣe ní kọ̀rọ̀ ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀.

27. Agiripa Ọba Aláyélúwà, ṣé ẹ gba àwọn wolii gbọ́? Mo mọ̀ pé ẹ gbà wọ́n gbọ́.”

28. Agiripa bá bi Paulu pé, “Kíákíá báyìí ni o rò pé o lè sọ mí di Kristẹni?”

29. Paulu dáhùn, ó ní, “Ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ Ọlọrun ni pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí ẹ rí bí mo ti rí lónìí, láìṣe ti ẹ̀wọ̀n yìí. Kì í ṣe ẹ̀yin nìkan, ṣugbọn gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí.”

30. Agiripa bá dìde pẹlu gomina ati Berenike ati gbogbo àwọn tí ó jókòó pẹlu wọn.

31. Wọ́n bọ́ sápá kan, wọ́n ń sọ fún wọn pé, “Ọkunrin yìí kò ṣe ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú tabi ẹ̀wọ̀n.”

32. Agiripa wá sọ fún Fẹstu pé, “À bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ siwaju Kesari.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 26