Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 25:14-27 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Wọ́n pẹ́ díẹ̀ níbẹ̀. Fẹstu wá fi ọ̀rọ̀ Paulu siwaju ọba. Ó ní, “Ọkunrin kan wà níhìn-ín tí Fẹliksi fi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

15. Nígbà tí mo lọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà àwọn Juu rojọ́ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ mí pé kí n dá a lẹ́bi.

16. Mo dá wọn lóhùn pé kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti fa ẹnikẹ́ni lé àwọn olùfisùn rẹ̀ lọ́wọ́ láì fún un ní anfaani láti fojúkojú pẹlu wọn, kí ó sì sọ ti ẹnu rẹ̀ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

17. Nígbà tí wọ́n bá mi wá síhìn-ín, n kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ní ọjọ́ keji mo jókòó ní kóòtù, mo pàṣẹ kí wọ́n mú ọkunrin náà wá.

18. Nígbà tí àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án dìde láti sọ̀rọ̀, wọn kò mẹ́nuba irú àwọn ọ̀ràn tí mo rò pé wọn yóo sọ.

19. Àríyànjiyàn nípa ẹ̀sìn oriṣa wọn, ati nípa ẹnìkan tí ń jẹ́ Jesu ni ohun tí wọn ń jà sí. Jesu yìí ti kú, ṣugbọn Paulu ní ó wà láàyè.

20. Ọ̀rọ̀ náà rú mi lójú; mo bá bi ọkunrin náà bí ó bá fẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, kí á ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà níbẹ̀.

21. Ṣugbọn Paulu ní kí á fi òun sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí Kesari yóo fi lè gbọ́ ẹjọ́ òun. Mo bá pàṣẹ kí wọ́n fi í sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí tí n óo fi lè fi ranṣẹ sí Kesari.”

22. Agiripa bá wí fún Fẹstu pé, “Èmi fúnra mi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkunrin náà.”Fẹstu dáhùn ó ní, “Ẹ óo gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ lọ́la.”

23. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Agiripa ati Berenike bá dé pẹlu ayẹyẹ. Wọ́n wọ gbọ̀ngàn ní ààfin pẹlu àwọn ọ̀gágun ati àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn ní ìlú. Fẹstu bá pàṣẹ kí wọ́n mú Paulu wá.

24. Fẹstu wá sọ pé, “Agiripa aláyélúwà ati gbogbo ẹ̀yin eniyan tí ẹ bá wa péjọ níbí. Ọkunrin tí ẹ̀ ń wò yìí ni gbogbo àwọn Juu ní Jerusalẹmu ati níbí ń yan eniyan wá rí mi nípa rẹ̀, tí wọn ń kígbe pé kò yẹ kí ó tún wà láàyè mọ́.

25. Ní tèmi n kò rí ohun kan tí ó ṣe tí ó fi jẹ̀bi ikú. Ṣugbọn nígbà tí òun fúnrarẹ̀ ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ sí ọ̀dọ̀ Kesari, mo pinnu láti fi í ranṣẹ.

26. Ṣugbọn n kò ní ohun kan pàtó láti kọ sí oluwa mi nípa rẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi mú un wá siwaju yín, pàápàá siwaju Agiripa aláyélúwà, kí n lè rí ohun tí n óo kọ nípa rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti yẹ ọ̀rọ̀ náà wò.

27. Mo rò pé kò bójú mu kí á fi ẹlẹ́wọ̀n ranṣẹ láìsọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 25