Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 24:4-16 BIBELI MIMỌ (BM)

4. N kò fẹ́ gbà yín ní àkókò títí, mo bẹ̀ yín kí ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbọ́ ohun tí a níláti sọ ní ṣókí.

5. Onijamba eniyan ni ọkunrin yìí; rúkèrúdò ni ó ń dá sílẹ̀ láàrin àwọn Juu ní gbogbo àgbáyé. Ọ̀gá ni ninu ẹgbẹ́ àwọn Nasarene.

6. A ká a mọ́ ibi tí ó ti fẹ́ mú ohun ẹ̀gbin wọ inú Tẹmpili, a bá mú un. [A fẹ́ jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí òfin wa.

7. Ṣugbọn ọ̀gágun Lisia wá fi ipá gbà á kúrò lọ́wọ́ wa, ni ó bá mú un lọ.

8. Òun ni ó pàṣẹ pé kí àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án wá siwaju yín.] Bí ẹ bá wádìí lẹ́nu òun fúnrarẹ̀, ẹ óo rí i pé òtítọ́ ni gbogbo ẹjọ́ rẹ̀ tí a fi sùn yín.”

9. Àwọn Juu náà gbè é lẹ́sẹ̀; wọ́n ní bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ rí.

10. Gomina wá mi orí sí Paulu. Paulu wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀. Ó ní:“Ó dùn mọ́ mi pé níwájú yín ni n óo ti sọ ti ẹnu mi. Nítorí mo mọ̀ pé ẹ ti ń ṣe onídàájọ́ ní orílẹ̀-èdè wa yìí fún ọpọlọpọ ọdún.

11. Kò ju ọjọ́ mejila lọ nisinsinyii tí mo lọ ṣọdún ní Jerusalẹmu. Ẹ lè wádìí èyí.

12. Ẹnìkan kò rí mi kí n máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn ninu Tẹmpili. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò rí mi pé mo kó àwọn eniyan jọ láti dá rúkèrúdò sílẹ̀, ìbáà ṣe ninu ilé ìpàdé ni tabi níbikíbi láàrin ìlú.

13. Wọn kò lè rí ohunkohun wí tí ẹ lè rí dìmú ninu ẹjọ́ tí wọn wá ń rò mọ́ mi lẹ́sẹ̀ nisinsinyii.

14. Ṣugbọn mo jẹ́wọ́ ohun kan fun yín: lóòótọ́ ni mò ń sin Ọlọrun àwọn baba wa ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Mo gba gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé Òfin ati ninu ìwé àwọn wolii.

15. Mo sì ń wojú Ọlọrun nítorí pé mo ní ìrètí kan náà tí àwọn ará ibí yìí pàápàá tí wọn ń rojọ́ mi ní, pé gbogbo òkú ni yóo jinde, ati ẹni rere ati ẹni burúkú.

16. Ìdí nìyí tí mo fi ń sa ipá mi kí ọkàn mi lè jẹ́ mi lẹ́rìí pé inú mi mọ́ sí Ọlọrun ati eniyan nígbà gbogbo.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 24