Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 23:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nítorí àwọn Sadusi sọ pé kò sí ajinde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí angẹli tabi àwọn ẹ̀mí; ṣugbọn àwọn Farisi gbà pé mẹtẹẹta wà.

9. Ni ariwo ńlá bá bẹ́ sílẹ̀. Àwọn amòfin kan ninu àwọn Farisi dìde, wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé, “Àwa kò rí nǹkan burúkú tí ọkunrin yìí ṣe. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀mí ni ó sọ̀rọ̀ fún un ńkọ́? Tabi angẹli?”

10. Nígbà tí àríyànjiyàn náà pọ̀ pupọ, ẹ̀rù ba ọ̀gágun pé kí wọn má baà fa Paulu ya. Ó bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ogun kí wọn wá fi agbára mú Paulu kúrò láàrin wọn, kí wọn mú un wọnú àgọ́ àwọn ọmọ-ogun lọ.

11. Ní òru ọjọ́ keji, Oluwa dúró lẹ́bàá Paulu, ó ní, “Ṣe ọkàn rẹ gírí. Gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ́rìí iṣẹ́ mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni o níláti jẹ́rìí nípa mi ní Romu náà.”

12. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Juu péjọ pọ̀ láti dìtẹ̀ sí Paulu. Wọ́n búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu.

13. Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ yìí ju bí ogoji lọ.

14. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà, wọ́n ní, “A ti jẹ́jẹ̀ẹ́, a sì ti búra pé a kò ní fẹnu kan nǹkankan títí a óo fi pa Paulu.

15. A fẹ́ kí ẹ̀yin ati gbogbo wa ranṣẹ sí ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé kí ó fi Paulu ranṣẹ sí yín nítorí ẹ fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fínnífínní. Ní tiwa, a óo ti múra sílẹ̀ láti pa á kí ó tó dé ọ̀dọ̀ yín.”

16. Ṣugbọn ọmọ arabinrin Paulu kan gbọ́ nípa ète yìí. Ó bá lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun, ó lọ ròyìn fún Paulu.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 23