Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 20:16-28 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nítorí Paulu ti pinnu láti wọkọ̀ kọjá Efesu, kí ó má baà pẹ́ pupọ ní Esia, nítorí ó ń dàníyàn pé bí ó bá ṣeéṣe, òun fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Pẹntikọsti ní Jerusalẹmu.

17. Láti Miletu, Paulu ranṣẹ sí Efesu kí wọ́n lọ pe àwọn alàgbà ìjọ wá.

18. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ bí mo ti lo gbogbo àkókò mi láàrin yín láti ìgbà tí mo ti kọ́kọ́ dé ilẹ̀ Esia.

19. Ẹ mọ̀ bí mo ti fi ìrẹ̀lẹ̀ ati omi ojú sin Oluwa ní ọ̀nà gbogbo ninu àwọn ìṣòro tí mo fara dà nítorí ọ̀tẹ̀ tí àwọn Juu dì sí mi.

20. Ẹ mọ̀ pé n kò dánu dúró láti sọ ohunkohun fun yín tí yóo ṣe yín ní anfaani; mò ń kọ yín ní gbangba ati ninu ilé yín.

21. Mò ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu ati àwọn Giriki pé kí wọn yipada sí Ọlọrun, kí wọn ní igbagbọ ninu Oluwa Jesu.

22. Nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti darí mi, mò ń lọ sí Jerusalẹmu láì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí mi níbẹ̀,

23. àfi pé láti ìlú dé ìlú ni Ẹ̀mí Mímọ́ ń fi àmì hàn mí pé ẹ̀wọ̀n ati ìyà ń dúró dè mí níbẹ̀.

24. Ṣugbọn n kò ka ẹ̀mí mi sí ohunkohun tí ó ní iye lórí fún ara mi. Ohun tí mò ń lépa ni láti parí iré ìje mi ati iṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Oluwa mi Jesu, èyí ni pé kí n tẹnu mọ́ ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.

25. “Wàyí ò, èmi gan-an mọ̀ pé gbogbo ẹ̀yin tí mo ti ń waasu ìjọba Ọlọrun láàrin yín kò tún ní fi ojú kàn mí mọ́.

26. Nítorí náà mo sọ fun yín lónìí yìí pé bí ẹnikẹ́ni bá ṣègbé ninu yín, ẹ̀bi mi kọ́.

27. Nítorí n kò dánu dúró láti sọ gbogbo ohun tí Ọlọrun fẹ́ fun yín.

28. Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 20