Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 2:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ìdààmú bá gbogbo àwọn eniyan, ó pá wọn láyà. Wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ èyí?”

13. Ṣugbọn àwọn mìíràn ń ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ní, “Wọ́n ti mu ọtí yó ni!”

14. Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.

15. Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni.

16. Ṣugbọn ohun tí Joẹli, wolii Ọlọrun ti sọ wá ṣẹ lónìí, tí ó wí pé,

17. ‘Ọlọrun sọ pé,“Nígbà tí ó bá di àkókò ìkẹyìn,n óo tú Ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo eniyan.Àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin yóo sọ àsọtẹ́lẹ̀àwọn ọdọmọkunrin yín yóo rí ìran,àwọn àgbà yín yóo sì lá àlá.

18. Àní, ní àkókò náà, n óo tú Ẹ̀mí misórí àwọn ẹrukunrin miati sí orí àwọn ẹrubinrin mi,àwọn náà yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.

19. N óo fi ohun ìyanu hàn lókè ọ̀run,ati ohun abàmì lórí ilẹ̀ ayé;ẹ̀jẹ̀, ati iná, ìkùukùu ati èéfín.

20. Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo di ẹ̀jẹ̀,kí ó tó di ọjọ́ ńlá tí ó lókìkí, ọjọ́ Oluwa.

21. Ní ọjọ́ náà gbogbo ẹni tí óbá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” ’

22. “Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.

23. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun ati ètò tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, a fi í le yín lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí àwọn aláìbìkítà fún Òfin kàn án mọ́ agbelebu, ẹ sì pa á.

24. Ṣugbọn Ọlọrun tú ìdè ikú, ó jí i dìde ninu òkú! Kò jẹ́ kí ikú ní agbára lórí rẹ̀.

25. Nítorí Dafidi sọ nípa rẹ̀ pé,‘Mo rí Oluwa níwájú mi nígbà gbogbo,ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún minítorí náà ohunkohun kò lè dà mí láàmú.

26. Nítorí náà inú mi dùn, mo bú sẹ́rìn-ín.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan ẹlẹ́ran-ara ni mí,sibẹ n óo gbé ìgbé-ayé mi pẹlu ìrètí;

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 2