Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 18:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan takò ó, tí wọn ń sọ ìsọkúsọ, ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀ sí wọn lójú, ó ní, “Ẹ̀jẹ̀ yín wà lọ́rùn yín. Ọwọ́ tèmi mọ́. Láti ìgbà yìí lọ èmi yóo lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.”

7. Ni ó bá kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ẹnìkan tí ó ń jẹ́ Titiu Jusitu, ẹnìkan tí ń sin Ọlọrun. Ilé rẹ̀ fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹlu ilé ìpàdé àwọn Juu.

8. Kirisipu, ẹni tí ń darí ètò ilé ìpàdé àwọn Juu gba Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ilé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni pupọ ninu àwọn ará Kọrinti; nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa, wọ́n gbàgbọ́, wọ́n bá ṣe ìrìbọmi.

9. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, Paulu rí ìran kan. Ninu ìran náà Oluwa sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, máa waasu, má dákẹ́.

10. Nítorí n óo wà pẹlu rẹ. Kò sí ẹni tí yóo fọwọ́ kàn ọ́ láti ṣe ọ́ níbi. Nítorí mo ní eniyan pupọ ninu ìlú yìí.”

11. Paulu gbé ààrin wọn fún ọdún kan ati oṣù mẹfa, ó ń kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

12. Ṣugbọn nígbà tí Galio di gomina Akaya, àwọn Juu fi ohùn ṣọ̀kan láti dìde sí Paulu. Wọ́n bá mú un lọ sí kóòtù níwájú Galio.

13. Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń kọ́ àwọn eniyan láti sin Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó lòdì sí òfin.”

14. Bí Paulu ti fẹ́ lanu láti fèsì, Galio sọ fún àwọn Juu pé, “Ẹ̀yin Juu, bí ó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan tabi ọ̀ràn burúkú kan ni ẹ mú wá, ǹ bá gbọ́ ohun tí ẹ ní sọ;

15. ṣugbọn tí ó bá jẹ́ àríyànjiyàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tabi orúkọ, tabi òfin yín, ẹ lọ rí sí i fúnra yín. N kò fẹ́ dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.”

16. Ni ó bá lé wọn kúrò ní kóòtù.

17. Ni gbogbo wọ́n bá mú Sositene, olórí ilé ìpàdé àwọn Juu, wọ́n ń lù ú níwájú kóòtù. Ṣugbọn Galio kò pé òun rí wọn.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 18