Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 18:10-21 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Nítorí n óo wà pẹlu rẹ. Kò sí ẹni tí yóo fọwọ́ kàn ọ́ láti ṣe ọ́ níbi. Nítorí mo ní eniyan pupọ ninu ìlú yìí.”

11. Paulu gbé ààrin wọn fún ọdún kan ati oṣù mẹfa, ó ń kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

12. Ṣugbọn nígbà tí Galio di gomina Akaya, àwọn Juu fi ohùn ṣọ̀kan láti dìde sí Paulu. Wọ́n bá mú un lọ sí kóòtù níwájú Galio.

13. Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń kọ́ àwọn eniyan láti sin Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó lòdì sí òfin.”

14. Bí Paulu ti fẹ́ lanu láti fèsì, Galio sọ fún àwọn Juu pé, “Ẹ̀yin Juu, bí ó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan tabi ọ̀ràn burúkú kan ni ẹ mú wá, ǹ bá gbọ́ ohun tí ẹ ní sọ;

15. ṣugbọn tí ó bá jẹ́ àríyànjiyàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tabi orúkọ, tabi òfin yín, ẹ lọ rí sí i fúnra yín. N kò fẹ́ dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.”

16. Ni ó bá lé wọn kúrò ní kóòtù.

17. Ni gbogbo wọ́n bá mú Sositene, olórí ilé ìpàdé àwọn Juu, wọ́n ń lù ú níwájú kóòtù. Ṣugbọn Galio kò pé òun rí wọn.

18. Paulu tún dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà ó dágbére fún àwọn onigbagbọ, ó bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria; Pirisila ati Akuila bá a lọ. Paulu gé irun rẹ̀ ní ìlú Kẹnkiria nítorí pé ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan.

19. Nígbà tí wọ́n dé Efesu, Paulu fi Pirisila ati Akuila sílẹ̀, ó lọ sinu ilé ìpàdé àwọn Juu, ó lọ bá àwọn Juu sọ̀rọ̀.

20. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún àkókò díẹ̀ sí i, ṣugbọn kò gbà.

21. Bí ó ti fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó ní, “N óo tún pada wá sí ọ̀dọ̀ yín bí Ọlọrun bá fẹ́.” Ó bá kúrò ní Efesu.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 18